1 Heṣekáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹẹ̀dọ́gbọ̀n (25) nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (25) orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ábíjà ọmọbìnrin Sékáríà.
2 Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí bàba rẹ̀ Dáfídì ti ṣe.
3 Ní osù àkọ́kọ́ ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, ó sì sí àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tún wọn ṣe.
4 Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Léfì, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà òorùn.
5 Ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin ọmọ Léfì! Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nísinsin yìí kí ẹ sì ya ile Olúwa Ọlọ́run sí mímọ́, kí ẹ sì kó ohun àìmọ́ bàbá jáde kúrò ní ibi mímọ́.