10 Nísinsìn yìí ó wà ní ọkàn mi láti bá Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìbínú rẹ̀ kíkan kí ó lè yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.
11 Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsìn yìí, nítorí tí Olúwa ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí.”
12 Nígbà náà àwọn ọmọ Léfì wọ̀nyí múra láti ṣe iṣẹ́:nínú àwọn ọmọ Kóhátì,Máhátì ọmọ Ámásà: àti jóẹ́lì ọmọ Ásáríyà;nínú àwọn ọmọ Mérárì,Kíṣì ọmọ Ábídì àti Ásáríyà ọmọ Jéháiéíèlì;nínú àwọn ọmọ Gésónì,Jóà, ọmọ símà àti Édẹ́nì ọmọ Jóà;
13 nínú àwọn ọmọ Élisáfánì,Ṣímírì àti Jégíèlì;nínú àwọn ọmọ Ásáfù,Sékáríà àti Mátaníyà;
14 nínú àwọn ọmọ Hémánì,Jéhíélì àti Ṣíméhì;nínú àwọn ọmọ Jédútùnì,Ṣémáíà àti Húsíélì.
15 Nigbà tí wọ́n sì ti kó ara wọn jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì lọ láti gbá ile Olúwa mọ́, gẹ́gẹ́ bí ọba ti paáláṣẹ, ẹ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Olúwa.
16 Àwọn àlùfaà sì wọ inú ilé Olúwa lọ́hùn ún lọ láti gbá a mọ́. Wọ́n sì gbé e jáde sí inú àgbàlá ilé Olúwa gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú ilé Olúwa. Àwọn ọmọ Léfì sì mú u wọ́n sì gbé e jáde sí gbangba odò Kédírónì.