17 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìyà sí mímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní osù kìn-ín-ní, àti ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà wọ́n sì dé ìloro Olúwa. Fún ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn síi, wọ́n sì ya ilé Olúwa sí mímọ́ fún rarẹ̀. Wọ́n sì parí ní ọjọ́ kẹ́rìndínlógún oṣù kìn-ín-ní.
18 Nígbà náà wọn sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Héṣékíà láti lọ jábọ̀ fún un: “Àwa ti gbá ilé Olúwa mọ́, pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú gbogbo ohun ẹbọ rẹ̀, àti tábìlì àkàrà ìfihàn, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò.
19 A ti pèsè àsì ti yà sí mímọ́ gbogbo ohun èlò tí ọba Áhásì ti sọ di aláìmọ́ nínú àìsòótọ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọba; nísinsìn yìí, wọ́n wà níwájú pẹpẹ Olúwa.”
20 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọba Hésékíà sì kó olórí àwọn ìjòyè jọ, ó sì lọ sókè ilé Olúwa.
21 Wọ́n sì mú akọ màlúù méje wá, àti àgbò méje, àti ọ̀dọ́ àgùntàn méje àti òbúkọ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba, fún ibi mímọ́ àti fún Júdà. Ọba pàsẹ fun àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Árónì, láti se èyí lórí pẹpẹ Olúwa.
22 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ: Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ: Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́ àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ.
23 Òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé wá síwájú ọba àti ìjọ ènìyàn, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn.