2 Kíróníkà 29:21-27 BMY

21 Wọ́n sì mú akọ màlúù méje wá, àti àgbò méje, àti ọ̀dọ́ àgùntàn méje àti òbúkọ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba, fún ibi mímọ́ àti fún Júdà. Ọba pàsẹ fun àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Árónì, láti se èyí lórí pẹpẹ Olúwa.

22 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ: Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ: Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́ àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ.

23 Òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé wá síwájú ọba àti ìjọ ènìyàn, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn.

24 Àwọn àlùfáà wọn sì pa Òbúkọ, wọ́n sì gbé ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún gbogbo Ísírẹ́lì, nítorí ọba ti pàsẹ kí a ṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹṣẹ fún gbogbo Íṣírẹ́lì.

25 Ó sì mú àwọn Léfì dúró nínú ilé Olúwa pẹ̀lú Kíḿbálì ohun èlò orin àti dùùrù ní ọ̀nà tí a ti palásẹ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Dáfídì àti Gádì aríran ọba àti Nátanì wòlíì: Èyí ni a pa lásẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa láti ọwọ́ àwọn wòlíì rẹ̀.

26 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì sì dúró pẹ̀lú ohun èlò orin Dáfídì, àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ipè wọn.

27 Hésékíà sì pa á láṣẹ láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ, bí ẹbọ sísun náà ti bẹ̀rẹ̀, orin sí Olúwa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú ohun èlò orin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì.