24 Nítorí Heṣekáyà, ọba Júdà, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún àgùntàn: Ọ̀pọlọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́.
25 Gbogbo ìjọ ènìyàn Júdà pẹ̀lú àwọn àlùfaà àti àwọn ọmọ Léfì, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn àlejò tí ó ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Júdà yọ̀.
26 Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jérúsálẹ́mù: nítorí láti ọjọ́ Sólómónì, ọmọ Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì, irú èyí kò sí ní Jérúsálẹ́mù.
27 Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà: a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àni sí ọ̀run.