2 Kíróníkà 31:12-18 BMY

12 Nígbà náà wọ́n fi tọkàntọkàn mú ìdáwó wọn wá ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn yíyà sọ́tọ̀. Kónánáyà ará Léfì wà ní ìdí nǹkan wọ̀nyí àti arákùnrin rẹ̀ Ṣíméhì jẹ́ àtẹ̀lé e rẹ̀ lóyè.

13 Jéhíélì, Áṣáṣíà, Náhátì, Ásáhélì, Jérímótì, Joábádì, Élíélì, Ísímákíà, Máhátì àti Bénáyà jẹ́ àwọn alábojútó lábẹ́ Konáníà àti Ṣíméhì arákùnrin rẹ̀ nípa ipá ọba Heṣekáyà àti Áṣáríyà oníṣẹ́ ti ó wà ní ìkáwọ́ ilé Ọlọ́run.

14 Kórè ọmọ ímínà ará Léfì Olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn, wà ní ìkáwọ́ àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi fún Ọlọ́run, pí pín ìdáwó tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀

15 Édẹ́nì, Miníámínì, Jéṣúà, Ṣemáyà, Ámáríyà àti Ṣekánáyà ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹ́gbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré.

16 Ní àfikún, wọ́n pín sí àwọn ọkùnrin àgbà ọdún mẹ́ta tàbi ọ̀pọ̀ tí orúkọ wọn wà nínu ìtàn ìdíle láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn. Gbogbo àwọn ti yóò wọ ilé Olúwa láti ṣe oríṣìí iṣẹ́ ti a gbàwọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn àti ìpín wọn.

17 Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Léfì ogún ọdún tàbí jùbẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpínnu àti ìpín wọn.

18 Wọ́n fi gbogbo àwọn ọmọ kékèké sí i, àwọn ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin gbogbo ará ìlu. Tí a kọ lẹ́sẹsẹ sínú ìtàn ìdílé yìí ti baba ńlá wọn fún ìrántí. Nítorí tí wọ́n ṣe òtítọ́ ní yíya ara wọn sí ọ̀tọ̀.