2 Kíróníkà 34:23-29 BMY

23 Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé,

24 ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Júdà.

25 Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibíyìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’

26 Sọ fún ọba Júdà, ẹni tí ó rán yín láti bèèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ti sọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n nì tí íwọ gbọ́:

27 Nítorí ọkàn rẹ̀ dúró ìwọ sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa nígbà tí ó gbọ́ ohun tí ó sọ lórí ibíyìí àti ènìyàn rẹ, nítorí ìwọ rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi tí o sì fa aṣọ rẹ ya, tí o sì lọ níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ ni Olúwa wí.

28 Nísinsinyìí, Èmi ó kó ọ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ àwọn baba rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kò sì ní rí gbogbo ibi tí èmi ó mú wá sórí ibíyìí àti lórí àwọn tí ń gbé ibẹ̀.’ ”Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé ìdáhùn rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ ọba.

29 Nígbà náà ọba sì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Júdà jọ àti Jérúsálẹ́mù.