1 Síwájú síi, Jósíà ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, Àjọ ìrékọjá náà ni wọ́n sì pa ẹran ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ní-ní.
2 Ó sì yàn àwọn àlùfáà sí iṣẹ́ wọn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú ní ìsìn ilé Olúwa.
3 Ó sì wí fún àwọn ọmọ Léfì, ẹni tí ó sọ fún gbogbo àwọn Ísírẹ́lì ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé Olúwa tí Sólómónì ọmọ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ti kọ́. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀. Nísinsìn yìí ẹ sin Olúwa Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.
4 Ẹ múra sílẹ̀ nípa ìdílé ní ẹsẹsẹ yín gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí a kọ́ láti ọwọ́ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ Sólómónì.
5 “Dúró ní ibi mímọ́ pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Léfì fún ọ̀kọ̀kan ìpín àwọn ìdílé àwọn ẹgbẹ́ ará ìlú, àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀.