2 Kíróníkà 35:1-7 BMY

1 Síwájú síi, Jósíà ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, Àjọ ìrékọjá náà ni wọ́n sì pa ẹran ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ní-ní.

2 Ó sì yàn àwọn àlùfáà sí iṣẹ́ wọn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú ní ìsìn ilé Olúwa.

3 Ó sì wí fún àwọn ọmọ Léfì, ẹni tí ó sọ fún gbogbo àwọn Ísírẹ́lì ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé Olúwa tí Sólómónì ọmọ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ti kọ́. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀. Nísinsìn yìí ẹ sin Olúwa Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.

4 Ẹ múra sílẹ̀ nípa ìdílé ní ẹsẹsẹ yín gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí a kọ́ láti ọwọ́ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ Sólómónì.

5 “Dúró ní ibi mímọ́ pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Léfì fún ọ̀kọ̀kan ìpín àwọn ìdílé àwọn ẹgbẹ́ ará ìlú, àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀.

6 Ẹ pa ẹran àjọ ìrékọjá náà, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì pèsè ẹ̀ran fún àwọn ẹgbẹ́ arákùnrin yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa paláṣẹ láti ọwọ́ Mósè.”

7 Jósíà sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ iye rẹ̀ ẹgbàámẹ́ẹ̀dógún ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọmọ ewurẹ́ fún ẹbọ ìrékọjá, àti pẹ̀lú ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n akọ màlúù (3,000) gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ohun ìní láti ọ̀dọ̀ ọba.