24 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbé e jáde kúrò nínú kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì gbé e sínú kẹ̀kẹ́ mìíràn, wọ́n sì gbé e wá sí Jérúsálẹ́mù, níbi tí ó ti kú, wọ́n sì sin ín sínú ọ̀kan nínú àwọn ibojì àwọn baba rẹ̀, gbogbo Júdà àti gbogbo Jérúsálẹ́mù sì sọ̀fọ̀ fún un.
25 Jeremáyà sì pohùn réré ẹkún fún Jósíà, gbogbo àwọn akọrin ọkùnrin àti gbogbo àwọn akọrin obìnrin sì ń sọ ti Jósíà nínú orin ẹkún wọn títí di òní. Èyí sì di àṣà ní Jérúsálẹ́mù, a sì kọọ́ sínú àwọn orin ẹkún.
26 Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jósíà àti ìwà rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a ti kọ sínu ìwé òfin Olúwa.
27 Gbogbo iṣẹ́ náà, àti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti Júdà.