19 Sólómónì pẹ̀lú ṣe gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Ọlọ́run:pẹpẹ wúràtábìlì èyí tí àkàrà ìfihàn wà lórí rẹ̀;
20 Àwọn ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe pẹ̀lú fìtílà wọn kí wọn lè máa jó gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ní iwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi lélẹ̀;
21 Pẹ̀lú ìtànná wúrà àti fìtílà àti ẹ̀mú (ni ó jẹ́ kìkìdá wúrà tí ó gbópọn);
22 Pẹ̀lú àlùmágàjí fìtílà, àti àwo-kòtò àti ṣíbí àti àwo-kòtò tùràrí àti àwọn ìlẹ̀kùn wúrà ti inú tẹ́ḿpìlì: àwọn ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ sí ibi mímọ́ jùlọ àti àwọn ìlẹ̀kùn àbáwọ inú gbọ̀ngàn ńlá.