1 Nígbà náà ni Sólómonì wí pé, “Olúwa ti sọ wí pé òun yóò máa gbé nínú ìkùku tí ó ṣú biribiri;
2 ṣùgbọ́n èmi ti kọ́ tẹ́ḿpìlì dáradára fún ọ ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láé.”
3 Ní ìgbà tí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì dúró níbẹ̀, ọba yíjú padà ó sì fi ìbùkún fún gbogbo wọn.
4 Nígbà náà ni ó sì wí pé:“Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dáfídì baba mi ṣẹ. Nitorí tí ó wí pé,
5 ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Ísirẹ́lì ènìyàn mi.
6 Ṣùgbọ́n nísinyìí èmi ti yan Jérúsálẹ́mù, kí orukọ mi leè wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dáfídì láti jọba lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’