2 Kíróníkà 6:23-29 BMY

23 Nígbà naà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dáhùn. Ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ, san padà fún ẹni tí ó jẹ̀bi nípa mímú padà wá sí orí òun tìkárarẹ̀ ohun tí ó ti ṣe. Ṣe ìdáláre fún olódodo, bẹ́ẹ̀ sì ni, fi fún-un gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀.

24 “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́sẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé Olúwa yìí,

25 Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jìn wọ́n kí o sì mú wọn padà wá sílé tí o ti fi fún wọn àti àwọn bàbá wọn.

26 “Nígbà tí a bá ti ọ̀run tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́sẹ̀ sí ọ, Nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú,

27 Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó má a rìn, kí o sì rán òjò lórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní.

28 “Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, irúgbà tàbí ẹlẹ́ǹgà, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá yọ wọ́n lẹ́nu nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú wọn, ohunkóhun, ìpọnjú tàbí àrùn lè wá,

29 Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé Olúwa yìí.