2 Kíróníkà 6:29-35 BMY

29 Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé Olúwa yìí.

30 Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run ibùgbé rẹ dáríjì, kí o sì pín fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí i gbogbo ohun tí ó ṣe, nígbà tí ìwọ ti mọ ọkàn rẹ̀ (nítorí ìwọ nìkan ni ó mọ okàn ènìyàn)

31 Bẹ́ẹ̀ ni kí wọn kí ó lè bẹ̀rù rẹ kí wọn kí ó sì rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń gbé nínú ilé tí o ti fi fún àwọn baba wa.

32 “Ní ti àwọn àlejò tí wọn kò sí lára àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ṣùgbọ́n tí wọ́n wá láti ọ̀nà jínjìn nítorí orúkọ ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá wá tí ó sì gbàdúrà lórí ilé Olúwa yìí.

33 Nigbà náà, gbọ́ láti ọ̀run àni láti ibi ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe ohun tí àwọn àlejò béèrè lọ́wọ́ rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ènìyàn ayé kí wọn lè mọ orúkọ rẹ kí wọn sì bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ ti se, kí wọn kí ó sì lè mọ̀ wí pé ilé yìí tí èmi ti kọ, orúkọ rẹ ni ó ń jẹ́.

34 “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá lọ sójú ogun lórí àwọn ọ̀ta wọn, nígbàkígbà tí o bá rán wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ lórí ìlú yìí tí ìwọ ti yàn àti ilé Olúwa tí èmi ti kọ́ fún orúkọ rẹ.

35 Nígbà náà gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.