39 Nígbà náà, láti ọ̀run, ibi ibùgbé rẹ, gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jìn wọn, tí ó ti dẹ́sẹ̀ sí ọ.
40 “Nísinsinyìí, Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ojú rẹ kí ó sí kí o sì tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ fún àdúrà sí ibíyí.
41 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí dìdé, Olúwa Ọlọ́run mi, sí ibi ìsinmi rẹ,ìwọ àti àpótí ẹ̀rí agbára rẹ.Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, Olúwa Ọlọ́run mi, kí o wọ̀ wọ́n lásọ pẹ̀lú ìgbàlà,jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ kí inú wọn kí ó dùn nínú ilé rẹ.
42 Olúwa Ọlọ́run mi, má ṣe kọ̀ ẹni àmìn òróró rẹ.Rántí ìfẹ́ ńlá tí ó ṣe ìlérí fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ.”