2 Kíróníkà 6:4-10 BMY

4 Nígbà náà ni ó sì wí pé:“Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dáfídì baba mi ṣẹ. Nitorí tí ó wí pé,

5 ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Ísirẹ́lì ènìyàn mi.

6 Ṣùgbọ́n nísinyìí èmi ti yan Jérúsálẹ́mù, kí orukọ mi leè wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dáfídì láti jọba lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’

7 “Baba mi Dáfídì ti ní-in lọ́kàn láti kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ Olúwa, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

8 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Dáfídì baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ tẹ́ḿpìlì yìí fún orúkọ mi, ìwọ ṣe ohun dáradára láti ní èyí ní ọkàn rẹ̀.

9 Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ tẹ́ḿpìlì náà, bí kò ṣe ọmọ rẹ, ẹni tí o jẹ́ ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ: òun ni yóò kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ mi.’

10 “Olúwa sì ti mú ìléri rẹ̀ ṣẹ. Èmi ti dìde ní ipò Dáfídì baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.