14 Tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn.
15 Nísisinyí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbíyìí.
16 Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé.
17 “Ní ti bí ìwọ bá rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ ti ṣe, tí o sì ṣe gbogbo ohun tí mo palásẹ, tí ìwọ sì ṣe àkíyèsí àṣẹ mi láti ọ̀run:
18 Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe pẹ̀lú Dáfídì baba rẹ nígbà tí mo bá a dá májẹ̀mu wí pé, ìwọ kò ní fẹ́ ẹnìkan kù láti ṣe alákòóso lórí Ísírẹ́lì.
19 “Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá yípadà tí o sì kọ òfin mi sílẹ̀ àti àṣẹ tí mo ti fi fún yín tí ẹ sì lọ sókè láti lọ sin Ọlọ́run mìíràn tí ẹ sì bọ wọ́n,
20 Nígbà náà ni èmi yóò fa Ísírẹ́lì tu kúrò láti ilẹ̀ mi, èyí tí èmi ti fi fún wọn, èmi yóò sì kọ̀ ilé náà sílẹ̀ èyí tí èmi ti yà sọ́tọ̀ fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ṣe ọ̀rọ̀ òwe, n ó fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin gbogbo ènìyàn,