Dáníẹ́lì 5:7-13 BMY

7 Ọba kígbe pé, kí wọn pe àwọn awòràwọ̀, àwọn onídán, àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, ọba sì sọ fún àwọn amòye Bábílónì pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí kí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹni náà ni a ó fi aṣọ eléṣèé àlùkò wọ̀ àti ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọrùn un rẹ̀, òun ni yóò sì ṣe olórí kẹta ní ìjọba à mi.”

8 Nígbà náà ni gbogbo àwọn amòye ọba wọ ilé, ṣùgbọ́n, wọn kò le ka àkọsílẹ̀ náà tàbí sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.

9 Nígbà náà ni Beliṣáṣárì ọba bínú gidigidi, ojú u rẹ̀ sì túbọ̀ dàrú síi. Ẹ̀rù sì ba àwọn ìjòyè rẹ̀.

10 Nígbà tí ayaba gbọ́ ohùn ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó wá ilé àsè wá. Ó wí pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Má ṣe jẹ́ kí inú un rẹ bàjẹ́, má sì ṣe jẹ́ kí ojú u rẹ fàro.

11 Ọkùnrin kan wà ní ìjọba à rẹ, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run, mímọ́ ń gbé inú un rẹ̀. Ní ìgbà ayé e bàbá à rẹ, òun ni ó ní ojú inú, òye àti ìmọ̀ bí i ti Ọlọ́run òun ni ọba Nebukadinéṣárì, bàbá rẹ̀ fi jẹ olórí àwọn onídán, awòràwọ̀, apògèdè àti aláfọ̀ṣẹ.

12 Ọkùnrin náà ni Dáníẹ́lì ẹni tí ọba ń pè ní Beliteṣáṣárì, ó ní ẹ̀mí tí ó tayọ, ìmọ̀ àti òye, àti agbára láti túmọ̀ àlá, ó máa ń ṣe àlàyé àlá àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá dojúrú, ránsẹ́ pè é, yóò sì sọ nǹkan tí àkọsílẹ̀ ìwé náà túmọ̀ sí.”

13 Nigbà náà ni a mú Dáníẹ́lì wá ṣíwájú ọba, ọba sì sọ fún-un wí pé, “Ṣé ìwọ ni Dáníẹ́lì, ọ̀kan lára àwọn tí bàbá mi mú ní ìgbékùn láti Júdà!