1 Ní ọdun kìn-ín-ní Dáríúsì ọmọ Áhásúérésì, ẹni tí a bí ní Médíà, òun ló jẹ ọba lórí ìjọba Bábílónì.
2 Ní ọdun kìn-ín-ní ijọba rẹ̀, èmi Dáníẹ́lì fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí wòlíì Jeremáyà, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jérúsálẹ́mù yóò fi wà ní ahoro.
3 Nígbà náà, ni mo yípadà sí Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú ààwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.
4 Mo gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé:“Iwọ Olúwa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.
5 Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀.
6 Àwa kò fetí sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ sí àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé àti àwọn baba wa, àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà.