30 Bákan náà ìwọ yóò sì mu Úrímù àti Tímímù sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Árónì nígbàkúgbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Árónì yóò sì máa ru ohun ti a ń fi se ìpinu fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọkàn rẹ̀ nígbàgbogbo níwájú Olúwa.
31 “Ìwọ yóò sìṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù éfódì náà ní kìkì aṣọ aláró,
32 pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrin rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìsẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya.
33 Ṣe pómégánátè ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò àti ti òdòdó yí ìsẹ́ti ọ̀já àmùrè náà ká, pẹ̀lú aago wúrà láàrin wọn.
34 Àwọn aago wúrà àti àwọn pómégánátè ni kí ó yí ìsẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká.
35 Árónì gbọdọ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí o bá ń sisẹ́. A ó sì máa gbọ́ ìró àwọn agogo nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ níwájú Olúwa àti nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀, kí ó má ba à kú.
36 “Ìwọ yóò sì ṣe àwo kìkì wúrà, ìwọ yóò sì fín sára rẹ̀ bí, fífín èdìdì àmì pé: ‘Mímọ́ sí Olúwa.’