3 Gbé àpótí ẹ̀rí sí inú rẹ̀, kí ó sì bo àpótí náà pẹ̀lú aṣọ títa.
4 Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì tò àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí. Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀.
5 Gbé pẹpẹ wúrà ti tùràrí sí iwájú àpótí ẹ̀rí, kí o sì fi aṣọ títa ẹnu ọ̀nà sí ara àgọ́ náà.
6 “Gbé pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun sí iwájú ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà, Àgọ́ àjọ;
7 gbé agbada sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, kí o sì fi omi sí inú rẹ̀.
8 Gbé àgbàlá ró yìí ka, kí ó sì fi aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà.
9 “Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára Àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀sọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́.