1 Ní òru ọjọ́ náà ọba kò le è ṣùn; nítorí náà, ó pàṣẹ kí wọn mú ìwé ìrántí wá, àkọsílẹ̀ ìjọba rẹ̀, wọ́n mú un wá wọ́n sì kàá síi létí.
2 Wọ́n rí àkọsílẹ̀ níbẹ̀ pé Módékáì tí sọ àṣírí Bígítanà àti Térésì, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, tí wọ́n ń gbérò láti pa ọba Ṣérísésì.
3 Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí Módékáì ti gbà fún èyí?”Àwọn ìránṣẹ́ẹ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Kò tíì sí ohun tí a ṣe fún-un.”
4 Ọba wí pé, “Taa ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí Hámánì ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa ṣíṣo Módékáì lórí igi tí ó ti rì fún-un.
5 Àwọn ìránṣẹ́ẹ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hámánì ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.”Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé wá.”