11 Àṣẹ ọba sì dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní gbogbo ìlú láti kó ara wọn jọ kí wọn sì dáàbò bo ara wọn; láti pa, láti run àti láti kọlu ogunkógun orílẹ̀ èdè kórílẹ̀ èdè kankan tàbí ìgbéríko tí ó bá fẹ́ kọ lù wọ́n, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn; kí ẹ sì kó gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀taa wọn.
12 Ọjọ́ tí a yàn fún àwọn Júù ní gbogbo agbégbé ọba Ṣéríṣésì láti ṣe nǹkan yìí ni ọjọ́ kẹtàlá èyí tí í ṣe oṣu kejìlá, oṣù Ádárì.
13 Ọkàn ìwé àṣẹ náà ni kí a gbé jáde gẹ́gẹ́ bí òfin ní gbogbo ìgbéríko kí ẹ sì jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn ìlú nítorí àwọn Júù yóò leè múra ní ọjọ́ náà láti gbẹ̀san fún ara wọn lára àwọn ọ̀taa wọn.
14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ ayaba bí àṣà tí wọ́n ń gun ẹṣin ọba, sáré jáde, wọ́n sáré lọ nípa àṣẹ ọba. A sì tún gbé àṣẹ náà jáde ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà.
15 Módékáì sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú eléṣèé àlùkò dáradára, ìlú Ṣúṣà sì ṣe àjọyọ̀ ńlá.
16 Àsìkò ìdùnú àti ayọ̀, inú dídùn àti ọlá ni ó jẹ́ fún àwọn Júù.
17 Ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú, ní gbogbo ibi tí àṣẹ ọba dé, ni ayọ̀ àti inú dídùn ti wà láàrin àwọn Júù, wọ́n sì ń ṣe àsè àti àjọyọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tó kù sọ ara wọn di Júù nítorí ẹ̀rù àwọn Júù bà wọ́n.