1 Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Ádárì, tí ó yẹ kí a mú àṣẹ tí ọba pa wá sí ìmúṣẹ. Ní ọjọ́ yìí ni ọ̀tá àwọn Júù rò pé àwọn yóò borí i wọn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ti yìí padà, àwọn Júù sì na ọwọ́ agbára tó ga lórí àwọn tí ó kóòríra wọn.
2 Àwọn Júù pé jọ ní àwọn ìlú u wọn ní gbogbo agbégbé ọba Ṣéríṣésì láti kọlu àwọn tó ń wá ìparun wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dojú kọ wọ́n, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ìlú tó kù ń bẹ̀rù u wọn.
3 Gbogbo àwọn ọlọ́lá ìgbéríko, àwọn alákòóso, àwọn baálẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ ọba ran àwọn Júù lọ́wọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù u Módékáì.
4 Módékáì sì jẹ́ ẹni pàtàkì ní ààfin, òkìkíi rẹ̀ sì tàn jákè jádò àwọn ìgbéríko, ó sì ní agbára kún agbára.