9 Parimásítà, Áríṣáyì, Árídáyì àti Fáíṣátà,
10 Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hámánì, ọmọ Hámédátà, ọ̀ta àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ ọ wọn lé ìkógún un wọn.
11 Ní ọjọ́ náà gan-an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà wá fún ọba.
12 Ọba sì sọ fún Ẹ́sítà ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀ta (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hámánì ní ilé ìṣọ́ Ṣúṣà run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tó kù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.”
13 Ẹ́sítà sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.”
14 Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Ṣúṣà, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hámánì kọ́.
15 Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ní Ṣúṣà, Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ ọ wọn lé ìkógún un wọn.