1 Lẹ́yìn ikú u Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Jóṣúà ọmọ Núnì, olùrànlọ́wọ́ ọ Móṣè:
2 “Mósè ìránṣẹ́ ẹ̀ mi ti kú. Nísinsìn yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ múra láti kọjá odò Jọ́dánì lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Ísírẹ́lì.
3 Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹṣẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Móṣè.
4 Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti ihà u Lẹ́bánónì, àti láti odò ńlá, ti Éfúrétì—gbogbo orílẹ̀ èdè Hítì títí ó fi dé Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.
5 Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú ù rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mósè, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú ù rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.