17 Nígbà tí wọ́n sọ fún Jósúà pé, a ti rí àwọn ọba máràrùn, ti ó fara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Mákédà,
18 ó sì wí pé, “Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ.
19 Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe dúró! Ẹ lépa àwọn ọ̀ta yín, ẹ kọlù wọ́n làti ẹyìn, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó dé ìlú wọn, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín tí fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”
20 Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà àti àwọn ọmọ ogun pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ ogun àwọn ọba máràrùn run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn.
21 Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Jóṣúà ní ibùdó ogun ní Mákédà ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Ísírẹ́lì.
22 Jósúà sì wí pe, “Ẹ ṣi ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba máràrùn jáde wá fún mi.”
23 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúró nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jérúsálẹ́mù, Hẹ́búrónì, Jámútù, Lákíṣì àti Égílónì.