Jóṣúà 10:20-26 BMY

20 Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà àti àwọn ọmọ ogun pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ ogun àwọn ọba máràrùn run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn.

21 Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Jóṣúà ní ibùdó ogun ní Mákédà ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Ísírẹ́lì.

22 Jósúà sì wí pe, “Ẹ ṣi ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba máràrùn jáde wá fún mi.”

23 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúró nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jérúsálẹ́mù, Hẹ́búrónì, Jámútù, Lákíṣì àti Égílónì.

24 Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Jóṣúà wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ sún mọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn.

25 Jóṣúà sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni Olúwa yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀ta yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.”

26 Nígbà náà ni Jóṣúà kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba máràrùn náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́.