1 Nígbà tí Jábínì ọba Hásórù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó ránṣẹ́ sí Jóbábù ọba Madónì, sí ọba Ṣímírónì àti Ákíṣáfù,
2 àti sí àwọn ọba ìhà àríwá tí wọ́n wà ní orí òkè ní aginjù, gúsù ti Kínérótù, ní ẹsẹ̀ òkè ìwọ̀-oòrùn àti ní Nafotu Dórì ní ìwọ̀-oòrùn;
3 sí àwọn ará Kénánì ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Ámórì, Hítì, Pérísì àti Jébúsì ní orí òkè; àti sí àwọn Hífì ní ìsàlẹ̀ Hámónì ní agbégbé Mísípà.
4 Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun
5 Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Mérómù láti bá Ísírẹ́lì jà.