11 Wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀. Wọ́n sì pa wọ́n run pátapáta, wọn kò sì fi ohun alàyè kan sílẹ̀; ó sì fi iná sun Hásóri fúnrarẹ̀.
12 Jóṣúà sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n. Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ.
13 Sí bẹ̀ Ísírẹ́lì kò sùn ọ̀kankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkè kékèké, àyàfi Hásórì nìkan tí Jóṣúà sun.
14 Àwọn ará Ísírẹ́lì sì kó gbogbo ìkógún àti ohun ọ̀sìn ti ìlú náà fún ara wọn. Wọ́n sì fi idà pa gbogbo ènìyàn títí wọ́n fi run wọ́n pátapáta, kò sí ẹni tí ó wà láàyè.
15 Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mósè pàṣẹ fún Jóṣúà, Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mósè.
16 Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà gba gbogbo ilẹ̀ náà: ilẹ̀ òkè, gbogbo Nẹ́gébù, gbogbo agbégbé Gósénì, ẹsẹ̀ òkè ti ìwọ̀-oòrùn, aginjù àti àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ísírẹ́lì,
17 láti òkè Hálakì títí dé òkè Séírì, sí Báálì-Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì ní ìsàlẹ̀ òkè Hámónì. Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n.