7 Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yọ sí wọn ní òjijì ní ibi omi Meromù, wọ́n sì kọlù wọ́n,
8 Olúwa sì fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn ní gbogbo ọ̀nà títí dé Sídónì ńlá, sí Mísíréfótì-Máímù, àti sí Àfonífojì Mísípà ní ìlà-óòrùn, títí tí kò fi ku ẹnìkankan sílẹ̀.
9 Jóṣúà sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ: Ó sì já iṣan ẹ̀yìn ẹsẹ̀ ẹṣin wọn ó sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.
10 Ní àkókò náà Jóṣúà sì padà sẹ́yìn, ó sì ṣẹ́gun Hásórù, ó sì fi idà pa ọba rẹ̀. (Hásóri tí jẹ́ olú fún gbogbo àwọn ìlú wọ̀nyí Kó tó di àkókò yí.)
11 Wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀. Wọ́n sì pa wọ́n run pátapáta, wọn kò sì fi ohun alàyè kan sílẹ̀; ó sì fi iná sun Hásóri fúnrarẹ̀.
12 Jóṣúà sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n. Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ.
13 Sí bẹ̀ Ísírẹ́lì kò sùn ọ̀kankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkè kékèké, àyàfi Hásórì nìkan tí Jóṣúà sun.