2 Ní Sílò, ní Kénánì, wọn sọ fún wọn pé, “Olúwa pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.”
3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní ti wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.
4 Ìpín kìn-ín-ni wà fún àwọn ọmọ Kóhátì, ní agbo ilé, agbo ilé. Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Árónì àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara Símónì àti Bẹ́ńjámínì.
5 Ìyòókù àwọn ọmọ Kóhátì ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù, Dánì àti ìdajì Mánásè.
6 Àwọn ẹ̀yà Gásónì ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara ẹ̀yà Ísákárì, Áṣíérì, Náfitalì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní Básánì.
7 Àwọn ọmọ Mérárì ní agbo ilé, agbo ilé ni wọ́n fún ní ìlú méjìlá láti ara ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Sébúlónì.
8 Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pín ìlú wọ̀nyí àti ilẹ̀ pápá oko tutù fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Móse.