1 Nígbà náà ni Jóṣúà pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì jọ ní Ṣékémù. Ó pe àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, onídájọ́ àti àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run.
2 Jóṣúà sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Térà bàbá Ábúráhámù àti Náhórì ń gbé ní ìkọjá odò, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà.
3 Ṣùgbọ́n mo mú Ábúráhámù baba yín kúrò ní ìkọjá odò mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kénánì, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Ísáákì,
4 Èmi sì fún ní Ísáákì, mo fún ní Jákọ́bù àti Ísáù, mo sì fún Ísáù ní ilẹ̀ orí òkè Séírì, Ṣùgbọ́n Jákọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì.
5 “ ‘Nígbà náà ni mo rán Mósè àti Árónì, mo sì yọ Éjíbítì lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde.