Jóṣúà 24:10-16 BMY

10 Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Bálámù, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín ṣíwájú àti ṣíwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

11 “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ ré kọjá Jọ́dánì, tí ẹ sì wá sí Jẹ́ríkò. Àwọn ará ìlú Jẹ́ríkò sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Ámórì, Pérísì, Kénánì, Hítì, Gígásì, Hífì àti Jébúsì. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

12 Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọbá Ámórì méjì. Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín.

13 Bẹ́ẹ̀ ni mo fún un yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣiṣẹ́ fún, àti àwọn ìlú tí ẹ̀ yin kò kọ́; ẹ sì ń gbé inú wọn, ẹ sì ń jẹ nínú ọgbà àjàrà àti ọgbà ólífì tí ẹ kò gbìn.’

14 “Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò àti ní Éjíbítì kúrò, kí ẹ sì máa sin Olúwa.

15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin Olúwa nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò, tàbí òrìṣà àwọn ará Ámórì, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, Olúwa ni àwa yóò máa sìn.”

16 Àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Kí a má ri tí àwa yóò fi kọ Olúwa sílẹ̀ láti sin òrìṣà.!