Jóṣúà 24:6-12 BMY

6 Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Éjíbítì, ẹ wá sí òkun, àwọn ará Éjíbítì lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun pupa.

7 Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárin yín àti àwọn ará Éjíbítì, ó sì mú òkun wá sí orí i wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Éjíbítì. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní ihà fún ọjọ́ pípẹ́.

8 “ ‘Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Ámórì tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jọ́dánì. Wọ́n bá yín jà, Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Èmí pa wọ́n run kúrò ní wájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn.

9 Nígbà tí Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù, múra láti bá Ísírẹ́lì jà, ó ránṣẹ́ sí Bálámù ọmọ Béóríù láti fi yín bú.

10 Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Bálámù, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín ṣíwájú àti ṣíwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

11 “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ ré kọjá Jọ́dánì, tí ẹ sì wá sí Jẹ́ríkò. Àwọn ará ìlú Jẹ́ríkò sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Ámórì, Pérísì, Kénánì, Hítì, Gígásì, Hífì àti Jébúsì. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

12 Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọbá Ámórì méjì. Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín.