Jóṣúà 7:13-19 BMY

13 “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárin yín, Ìwọ Ísírẹ́lì. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀ta a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò.

14 “ ‘Ní òwúrọ̀ kí ẹ mú ará yín wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí Olúwa bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan.

15 Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàṣọ́tọ̀ náà, a ó fi iná paárun, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Ísírẹ́lì!’ ”

16 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kéjì, Jóṣúà mú Ísírẹ́lì wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Júdà.

17 Àwọn agbo ilé e Júdà wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sérátì. Ó sì mú agbo ilé Sérátì wá ṣíwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Símírì.

18 Jóṣúà sì mú ìdílé Símírì wá ṣíwájú ní ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, a sì mú Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Símírì, ọmọ Sérà ti ẹ̀yà Júdà.

19 Nígbà náà ní Jóṣúà sọ fún Ákánì pé, “Ọmọ mi fi ògo fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí o sì fi ìyin fún un. Sọ fún mi ohun tí ìwọ ti ṣe, má ṣe fi pamọ́ fún mi.”