12 Jóṣúà sì ti fi bí ẹgbẹ̀rún márùn ún ọmọ ogun pamọ́ sí àárin Bétélì àti Áì, sí ìwọ̀-òòrùn ìlú náà.
13 Wọ́n sì yan àwọn ọmọ ogun sí ipò wọn, gbogbo àwọn tí ó wà ní ibùdó lọ sí àríwá ìlú náà àti àwọn tí ó ṣápamọ́ sí ìwọ̀-òrùn rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà Jóṣúà lọ sí àfonífojì.
14 Nígbà tí ọba Áì rí èyí, òun àti gbogbo ọkùnrin ìlú náà yára jáde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti pàdé ogun Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aginjù. Ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àwọn kan wà ní ibùba ní ẹ̀yìn ìlú náà.
15 Jóṣúà àti gbogbo àwọn Ísírẹ́lì sì ṣe bí ẹni tí a lé padà níwájú wọn, wọ́n sì ṣá gba ọ̀nà ihà.
16 A sì pe gbogbo àwọn ọkùnrin Áì jọ láti lépa wọn, wọ́n sì lépa Jóṣúa títí wọ́n fi tàn wọ́n jáde nínú ìlú náà.
17 Kò sì ku ọkùnrin kan ní Áì tàbi Bétélì tí kò tẹ̀lé Ísírẹ́lì. Wọ́n sì fi ìlẹ̀kùn ibodè náà sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n sì ń lépa àwọn ará Ísírẹ́lì.
18 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Jóṣuà pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọ rẹ sí Áì, nítorí tí èmi yóò fi ìlú náà lé ọ ní ọwọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà sì na ọ̀kọ̀ ọwọ́ ọ rẹ̀ sí Áì.