15 Jóṣúà àti gbogbo àwọn Ísírẹ́lì sì ṣe bí ẹni tí a lé padà níwájú wọn, wọ́n sì ṣá gba ọ̀nà ihà.
16 A sì pe gbogbo àwọn ọkùnrin Áì jọ láti lépa wọn, wọ́n sì lépa Jóṣúa títí wọ́n fi tàn wọ́n jáde nínú ìlú náà.
17 Kò sì ku ọkùnrin kan ní Áì tàbi Bétélì tí kò tẹ̀lé Ísírẹ́lì. Wọ́n sì fi ìlẹ̀kùn ibodè náà sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n sì ń lépa àwọn ará Ísírẹ́lì.
18 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Jóṣuà pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọ rẹ sí Áì, nítorí tí èmi yóò fi ìlú náà lé ọ ní ọwọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà sì na ọ̀kọ̀ ọwọ́ ọ rẹ̀ sí Áì.
19 Bí ó ti ṣe èyí tán, àwọn ọkùnrin tí ó ba sì dìde kánkán kúrò ní ipò wọn, wọ́n sáré ṣíwájú. Wọn wọ ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára ti iná bọ̀ ọ́.
20 Àwọn ọkùnrin Áì bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, àyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Ísírẹ́lì tí wọ́n tí ń sálọ sí ihà ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn.
21 Nígbà tí Jóṣúà àti gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì rí i pé àwọn tí ó ba ti gba ìlú náà, tí èéfín ìlú náà sì ń gòkè, wọ́n yí padà wọ́n sì kọlu àwọn ọkùnrin Áì.