9 “ ‘Gàárì ẹranko tí ẹni náà bá gùn yóò di àìmọ́.
10 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó wà lábẹ́ ọkùnrin náà di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ ara rẹ̀. Yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
11 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ọkùnrin tí ó ní ìṣunjáde ní ara rẹ̀ bá farakàn láì fi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
12 “ ‘Ìkòkò amọ̀ tí ọkùnrin náà bá fọwọ́ kàn ni kí ẹ fọ́, gbogbo ohun èlò igi tí ó fọwọ́ kàn ni kí ẹ fi omi sàn.
13 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí a bá wẹ̀ nù kúrò nínú ìṣunjáde rẹ̀ gbọdọ̀ ka ọjọ́ méje fún àwọn ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́: kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀: yóò sì di mímọ́.
14 Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, kí ó sì wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa, kí ó sì kó wọn fún àlùfáà.
15 Kí àlùfáà fi wọ́n rúbọ: ọ̀kan fún ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ọrẹ ẹbọ sísun níwájú Olúwa ní ipò ọkùnrin náà nítorí ìṣunjáde rẹ̀.