25 Lẹ́yìn èyí, kí àlùfáà ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ẹ̀jẹ̀ yóòkù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ
26 Kí ó sun gbogbo ọ̀rá rẹ̀ lórí pẹpẹ bí ó se sun ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà. Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹsẹ ọkùnrin náà, a ó sì dárí jìn-ín.
27 “ ‘Bí ènìyàn nínú àwọn ará ìlú bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì se ohun tí kò yẹ sí ọkan nínú àwọn òfin Olúwa, ó jẹ̀bi.
28 Nígbà tí a bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
29 Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lórí ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó sì pa á níbi ẹbọ sísun.
30 Àlùfáà yóò sì ti ìka rẹ̀ bọ́ ẹ̀jẹ̀ náà, yóò fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ.
31 Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá ẹran náà gẹ́gẹ́ bó ṣe yọ ọ̀rá ẹran fún ọrẹ àlàáfíà. Kí àlùfáà sì sun ọ̀rá yìí lórí pẹpẹ bí òórùn dídùn sí Olúwa. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, a ó sì dárí jìn-ín.