1 Nísinsinyìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù, àwọn ènìyàn tó kù sì dìbò láti mú ẹnì kọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tó kù yóò dúró sí àwọn ìlúu wọn.
2 Àwọn ènìyàn súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn láti gbé ní Jérúsálẹ́mù.
3 Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì ń gbé àwọn ìlúu Júdà, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìníi rẹ̀ ní àwọn ìlú náà.
4 Nígbà tí àwọn ènìyàn tó kù nínú àwọn Júdà àti Bẹ́ńjámínìn ń gbé ní Jérúsálẹ́mù):Nínú àwọn ọmọ Júdà:Átaáyà ọmọ Úṣáyà ọmọ Ṣekaráyà, ọmọ Ámáráyà, ọmọ Ṣefatayà, ọmọ Máhálálélì, ìran Pérésì;