Nehemáyà 12:35-41 BMY

35 Pẹ̀lú àwọn àlùfáà díẹ̀ pẹ̀lú ipè (kàkàkí), pẹ̀lúu Ṣakaráyà ọmọ Jónátanì, ọmọ Ṣémáyà, ọmọ Matanáyà, ọmọ Míkáyà, ọmọ Ṣákúrì, ọmọ Áṣáfì,

36 Àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀—Ṣémáyà, Áṣárélì, Míláláì, gíláláì, Mááì, Nétanélì, Júdà àti Hánánì—pẹ̀lú ohun èlò orin bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run. Éṣírà akọ̀wé ni ó sáájúu wọn bí wọ́n ti ń tò lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́.

37 Ní ẹnu ibodè oríṣun wọ́n ti ń lọ tààrà sí ọ̀nà ní orí àtẹ̀gùn ìlú Dáfídì ní orí òkè tí ó kángun sí odi, wọ́n sì gba ẹ̀gbẹ́ ilée Dáfídì kọjá títí dé ẹnu ibodè omi ní ìhà ìlà oòrùn.

38 Àwọn ẹgbẹ́ akọrin kejì gba ọ̀nà òdì kejì lọ. Mo tẹ̀lé wọn ní orí odi, pẹ̀lú ìdajì àwọn ènìyàn, kọjá ilé ìṣọ́ ìléru lọ sí odi fífẹ̀,

39 Kọjá ẹnu ibodè Éúfúrẹ́mù ibodè Jéṣánà, ẹnu ibodè ẹja, ilé ìṣọ́ Hánánélì àti ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn—ún, títí dé ẹnu ibodè àgùntàn. Wọ́n sì dúró ní ibodè ìṣọ́.

40 Àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì tí wọ́n dúpẹ́ wà ní ààyè nínú ilé Ọlọ́run, èmi náà sì dúró ní ààyè mi pẹ̀lú ìdajì àwọn ìjòyè,

41 Àti àwọn àlùfáà—Élíákímù, Máṣéyà, Míníámínì, Míkáyà, Éliánáyì, Ṣaráyà àti Hananáyà pẹ̀lú àwọn ìpèe (kàkàkí) wọn.