9 Bákíbúkíyà àti Húnì, àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn dúró sí ìdojúkojú wọn nínú ìsìn.
10 Jéṣúà ni baba Jòíákímù, Jòíákímù ni baba Élíáṣíbù, Élíáṣíbù ni baba Jóíádà,
11 Jóíádà ni baba Jònátanì, Jònátanì sì ni baba Jádúà.
12 Ní ìgbé ayé Jòíakímù, wọ̀nyí ni àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn àlùfáà:ti ìdílé Ṣeráiáyà, Méráyà;ti ìdílé Jeremáyà, Hananíyà;
13 ti ìdílé Éṣírà, Mésúlámù;ti ìdílé Ámáráyà, Jéhóhánánì;
14 ti ìdílé Málúkì, Jònátanì;ti ìdílé Ṣékánáyà, Jóṣéfù;
15 ti ìdílé Hárímù, Ádíná;ti ìdílé Mérémótì Hélíkáyì;