1 Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Móṣè ṣókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú un rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn aráa Ámónì tàbí àwọn aráa Móábù sí àárin ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé.
2 Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Bálámù ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn-ún lé wọn lórí (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún).
3 Nígbà tí àwọn ènìyàn gbọ́ òfin yìí, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjòjì ènìyàn tí ó dara pọ̀ mọ́ wọn kúrò láàrin àwọn Ísírẹ́lì.
4 Ṣáájú èyí a ti fi Élíáṣíbù àlùfáà ṣe alákoṣo yàrá ìkó nǹkan ilé Ọlọ́run wa sí. Ó súnmọ́ Tóbíyà pẹ́kípẹ́ki.