Nehemáyà 13:1-6 BMY

1 Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Móṣè ṣókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú un rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn aráa Ámónì tàbí àwọn aráa Móábù sí àárin ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé.

2 Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Bálámù ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn-ún lé wọn lórí (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún).

3 Nígbà tí àwọn ènìyàn gbọ́ òfin yìí, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjòjì ènìyàn tí ó dara pọ̀ mọ́ wọn kúrò láàrin àwọn Ísírẹ́lì.

4 Ṣáájú èyí a ti fi Élíáṣíbù àlùfáà ṣe alákoṣo yàrá ìkó nǹkan ilé Ọlọ́run wa sí. Ó súnmọ́ Tóbíyà pẹ́kípẹ́ki.

5 Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹ́ḿpìlì àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Léfì, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lúu gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà.

6 Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jérúsálẹ́mù, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Aritaṣéṣéṣì ọba Bábílónì ni mo padà tọ ọba lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀.