7 Mo sì padà sí Jérúsálẹ́mù. Níhìn-ín ni mo ti mọ̀ nípa onírúurú ohun búburú tí Élíásíbù ti ṣe ní ti pípèṣè yàrá fún Tóbíyà nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run.
8 Kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, mo kó gbogbo ohun èlò ìdílée Tóbíyà dà síta láti inú iyàrá náà.
9 Mo pàṣẹ kí wọn ya àwọn iyàrá náà sí mímọ́, mo sì kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run padà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti tùràrí.
10 Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Léfì, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ẹ wọn.
11 Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ọ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀.
12 Gbogbo Júdà mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó—nǹkan sí.
13 Mo sì fi àlùfáà Ṣelemáyà, Ṣádókà akọ̀wé àti ọmọ Léfì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedáyà ṣe alákóṣo àwọn yàrá ìkó—nǹkan sí. Mo sì yan Hánánì ọmọ Ṣákúrì, ọmọ Mátanáyà bí olùrànlọ́wọ́ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn.