1 Élíṣíbù olórí àlùfáà àti àwọn àlùfáà arákùnrin rẹ̀ lọ ṣiṣẹ́, wọ́n sì tún ibodè Àgùntàn mọ. Wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn dúró sí ibi tí ó yẹ, wọ́n mọ ọ́n títí dé ilé ìṣọ́ Ọgọ́rùn ún, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ títí dé ilé ìṣọ́ gíga Hánálélì
2 Àwọn ọkùnrin Jẹ́ríkò sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣákúrì ọmọ Ímírì sì mọ ní ẹ̀gbẹ̀ àwọn ọkùnrin Jẹ́ríkò.
3 Àwọn ọmọ Háṣénáyà ni wọ́n mọ Ìbodè Ẹja. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn rẹ̀, ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè e rẹ̀ sí ààyè e wọn.
4 Mérémótì ọmọ Úráyà, ọmọ Hákóṣì tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn mọ. Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Mésúlámù ọmọ Bérékíà, ọmọ Méṣéábélì tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn mọ. Bákan ńaà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣádókù ọmọ Báánà náà tún odi mọ.