26 àti àwọn ìránṣẹ́ẹ tẹ́ḿpìlì tí ó ń gbé ní òkè Ófélì ṣe àtúnṣe títí dé ibi ọ̀kánkán ibodè omi sí ìhà ìlà oòrùn àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde.
27 Lẹ́yìn wọn ni àwọn ènìyàn Tékóà tún apá mìíràn ṣe, láti ilé ìṣọ́ ńlá tí ó yọ sóde títí dé ògiri Ófélì.
28 Àwọn àlùfáà ni ó ṣe àtúnṣe òkè ibodè ẹsin ṣe, ẹnì kọ̀ọ̀kan ní iwájú ilée rẹ̀.
29 Lẹ́yìn wọn, Ṣádókì ọmọ Ímérì tún ọ̀kánkán ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣémáyà ọmọ Ṣekanáyà, olùṣọ́ ibodè ìhà ìlà oòrùn ṣe àtúnṣe.
30 Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Hananáyà ọmọ Ṣelemáyà, àti Hánúnì ọmọ ẹ̀kẹfà Ṣáláfì, tún apá ibòmíràn ṣe. Lẹ́yìn wọn ni, Mésúlámù ọmọ Berekáyà tún ọ̀kánkán ibùgbé e rẹ̀ ṣe.
31 Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Mákíjà, ọ̀kan nínú àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn oníṣòwò, ní ọ̀kánkán ibodè àyẹ̀wò títí dé yàrá òkè kọ̀rọ̀;
32 àti láàárin yàrá òkè kọ̀rọ̀ àti ibodè àgùntàn ni àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà àti àwọn oníṣòwò tún ṣe.