Nehemáyà 3:5-11 BMY

5 Èyí tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn ni àwọn ọkùnrin Tẹ́kóà tún mọ, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́lá kò ṣe àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà lábẹ́ àwọn olórí wọn.

6 Jóádà ọmọ Páṣéà àti Mésúlámù ọmọ Béṣódáyà ni wọ́n tún ẹnu ibodè àtijọ́ ṣe. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn.

7 Lẹ́yìn in wọn ni àtúnṣe tún wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin Gíbíónì àti Mísípà: Mélátíà ti Gíbíónì àti Jádónì ti Mérónótì; àwọn ibi tí ó wà lábẹ́ àṣẹ baálẹ̀ agbègbè Éfúrétè.

8 Úsíélì ọmọ Hariháyà, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, tún ṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; àti Hananíyà, ọ̀kan lára awọn tí ó ń ṣe tùràrí, tún ṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e. Wọ́n mú Jérúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò títí dé Odi Gbígbòòrò.

9 Réfájà ọmọ Húrì, alákòóṣo ìdajì agbègbè Jérúsálẹ́mù, tún èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe.

10 Ní ẹ̀gbẹ́ èyí Jédáyà ọmọ Hárúmáfì tún èyí tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ilé rẹ̀ mọ, Hátúsì ọmọ Háṣábínéjà sì tún tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ.

11 Málíkíjà ọmọ Hárímù àti Háṣúbù ọmọ Páhátì—Móábù tún ẹ̀gbẹ́ kejì ṣe àti Ilé-ìṣọ́ Ìléru.