1 Nísinsìn yìí àwọn ènìyàn àti àwọn ìyàwó wọn kígbe ńlá sókè sí àwọn Júù arákùnrin wọn.
2 Àwọn kan ń wí pé, “Àwa àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa pọ̀; kí àwa kí ó le è jẹ, kí a sì wà láàyè, a gbọdọ̀ rí oúnjẹ.”
3 Àwọn mìíràn wí pé, “Àwa ti fi oko wa ọgbà àjàrà wa àti ilé wa dógò kí àwa kí ó lè rí oúnjẹ (ọkà) ní àkókò ìyàn.”
4 Ṣíbẹ̀ àwọn mìíràn wí pé, “Àwa ní láti yá owó láti san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba lórí àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa.